Òwe 7:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Mo ti tẹ́ ibùṣùn mipẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Éjíbítì.

17. Mo ti fi nǹkan Olóòórùn dídùn sí ibùṣùn mibí i míra, álóè àti kínámónì.

18. Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!

19. Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;ó ti lọ sí ìrìnàjò jínjìn.

20. Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

Òwe 7