Òwe 6:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́,tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.

5. Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo àgbọ̀nrín kúrò lọ́wọ́ ọdẹ,bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.

6. Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!

7. Kò ní olùdarí,kò sí alábojútó tàbí ọba,

8. síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjòyóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.

9. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ?Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?

Òwe 6