Òwe 6:21-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláéso wọ́n mọ́ ọrùn rẹ

22. Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ;nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùsọ́ rẹ;nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.

23. Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ àtùpà,ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀,àti ìtọ́niṣọ́nà ti ìbáwíni ọ̀nà sí ìyè

24. yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin oníṣekúṣekúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn aya tí ń rin ìrìnkurìn

25. Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ síi nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹtàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra,

26. nítorí Aṣẹ́wó yóò sọ ọ́ di àkàrà lásánlàsànẹ̀mí rẹ gan an sì ni alágbérè ń dọdẹ.

27. Ǹjẹ́ ènìyàn ha le è gbé iná lé orí itankí aṣọ rẹ̀ sì má jòó?

28. Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná?Kí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?

29. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya;kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láì jìyà.

30. Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalènítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.

Òwe 6