Òwe 6:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣààti àìní bí adigunjalè.

12. Ènìyàn kénìyàn àti ènìyàn búburú,tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,

13. tí ó ń sẹ́jú pàkòpàkò,ó ń fi ẹsẹ̀ ṣe àmìó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,

14. tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.

15. Nítorí náà ìdààmú yóò dé báa ní ìsẹ́jú akàn;yóò parun lójijì láì sí àtúnṣe.

16. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra,ohun méje ní ó jẹ́ ìríra síi:

Òwe 6