Òwe 5:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. N kò gbọ́ràn sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.

14. Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapátaní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn.”

15. Mu omi láti inú un kànga tìrẹOmi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ.

16. Ó ha yẹ kí omi ìṣun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nààti odò tí ń sàn lọ sí àárin ọjà?

17. Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjòjì láéláé.

18. Ǹjẹ́, kí oríṣun rẹ di àbùkù fún;kí ó sì yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.

Òwe 5