Òwe 4:20-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi

21. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójúpa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;

22. Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọnàti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn

23. Ju gbogbo nǹkan tó kù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́Nítorí òun ni oríṣun ìyè,

24. mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìṣọkúṣọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.

Òwe 4