Òwe 4:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;tọ́jú u rẹ̀ dáradára Nítorí òun ni ìyè rẹ.

14. Má ṣe gbé ẹṣẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburútàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.

15. Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ

16. Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú

17. Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búrurúwọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.

18. Ipa ọ̀nà Olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùntí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí

19. ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.

20. Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi

21. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójúpa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ;

Òwe 4