Òwe 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Tẹ́tí, Ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetí sílẹ̀ kí o sì ní òye sí i

2. Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooroNítorí náà má ṣe kọ ìkọ́ni mi sílẹ̀

3. Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi

4. Ó kọ́ mi ó sì wí pé“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,pa òfin mí mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.

5. Gba ọgbọ́n, gba òye,Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹṣẹ̀ kúrò nínú rẹ̀

Òwe 4