28. a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbáṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
29. “Àwọn ohun mẹ́ta ní n bẹ tí ń rìn rere,ohun mẹ́rin tí ń kọrí sí ibi rere,
30. Kìnnìún, alágbára láàrin ẹrankotí kì í sá fún ohunkóhun
31. Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ,àti ọba pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láyìíká rẹ̀.
32. “Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga,tàbí tí o bá ti gbèrò ibi,da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
33. Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wátí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jádebẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”