Òwe 30:26-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ehoro jẹ́ ẹ̀dá tí kò ní agbára púpọ̀ṣíbẹ̀ wọ́n ń ṣe ilé wọn sí ibi ihò àpáta;

27. Eṣú kò ní ọbaṣíbẹ̀ wọ́n ń jáde lọ papọ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

28. a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbáṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

29. “Àwọn ohun mẹ́ta ní n bẹ tí ń rìn rere,ohun mẹ́rin tí ń kọrí sí ibi rere,

30. Kìnnìún, alágbára láàrin ẹrankotí kì í sá fún ohunkóhun

31. Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ,àti ọba pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láyìíká rẹ̀.

Òwe 30