Òwe 30:25-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Àwọn èrà jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní agbára díẹ̀síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò

26. Ehoro jẹ́ ẹ̀dá tí kò ní agbára púpọ̀ṣíbẹ̀ wọ́n ń ṣe ilé wọn sí ibi ihò àpáta;

27. Eṣú kò ní ọbaṣíbẹ̀ wọ́n ń jáde lọ papọ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́

28. a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbáṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.

29. “Àwọn ohun mẹ́ta ní n bẹ tí ń rìn rere,ohun mẹ́rin tí ń kọrí sí ibi rere,

30. Kìnnìún, alágbára láàrin ẹrankotí kì í sá fún ohunkóhun

Òwe 30