Òwe 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi.Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.

2. Nítorí wọn yóò fún ọ ní ọjọ́ gígùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdúnkí ó sì mú ọ̀rọ̀ wá fún ọ.

3. Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláéso wọ́n mọ́ ọrùn rẹ,kọ wọ́n sí síléètì àyà rẹ.

4. Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojú rere àti orúkọ rerení ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.

Òwe 3