Òwe 26:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àsírí ara rẹ̀ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.

25. Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.

26. Ìkóríra rẹ le è farasin nípa ẹ̀tànṣùgbọ́n àsírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.

27. Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀.Bí ẹnikan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.

28. Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà,ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pani run.

Òwe 26