Òwe 24:29-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Má ṣe wí pé, “Mà á ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

30. Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,mo kọjá níbi oko aláìgbọ́n ènìyàn;

31. ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,koríko ti gba gbogbo oko náà

32. Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsímo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;

33. oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi

34. Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalèàti àìní bí olè.

Òwe 24