Òwe 24:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburúmá ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;

2. Nítorí ọkàn wọn ń gbérò ohun búburú,ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

3. Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́nípa òye sì ni ó ti fìdí múlẹ̀;

4. Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kúnpẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

Òwe 24