Òwe 23:29-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́?Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni aṣọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí?

30. Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí-wáìnì;àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò.

31. Ìwọ má ṣe wò ọtí-wáìnì nígbà tí ó pọ́n,nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,tí a gbé e mì, tí ó ń dùn.

Òwe 23