Òwe 22:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Yíyan orúkọ rere ṣàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.

2. Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọ pọ̀: Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.

3. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n níyà.

Òwe 22