13. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,òun tìkárarẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.
14. Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:àti owó-àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,dẹ́kun ìbínú líle.
15. Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
16. Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.
17. Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di talákà:ẹni tí ó fẹ́ ọtí-wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.
18. Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó-ìràpadà fún olódodo,àti olùrékọjá fún ẹni dídúró-ṣinṣin.
19. Ó sàn láti jókòó ní ihà ju pẹ̀lúoníjà obìnrin àti òṣónú lọ.
20. Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;ṣùgbọ́n ènìyàn aṣiwèrè (òmùgọ̀) jẹ ẹ́ run.
21. Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,òdodo, àti ọlá.
22. Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,ó sì bi ibi-gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.