Òwe 20:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkùìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

8. Nígbà tí ọba bá jókóò sórí ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.

9. Táni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́,mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?

10. Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ Olúwa kórìíra méjèèjì.

11. Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.

12. Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran Olúwa ni ó dá méjèèjì.

Òwe 20