Òwe 20:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà ẹ̀rú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyànṣùgbọ́n, a yọrí sí bi ẹnu tí ó kún fún èèpẹ̀.

18. Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀rànbí o bá ń jagun, gba ìtọ́ṣọ́nà.

19. Olófòófó dalẹ̀ àsírínítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ jù.

20. Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀,ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.

Òwe 20