Òwe 2:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí ilé rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà sí ikúọ̀nà rẹ̀ sì lọ sí ibi ẹ̀mí àwọn òkú.

19. Kò sẹ́ni tó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ tí ó padàtàbí tí ó rí ipa ọ̀nà ìyè.

20. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò rìn ní ọ̀nà àwọn ènìyàn rerekí o sì rìn ní ọ̀nà àwọn Olódodo

21. Nítorí ẹni dídúró ṣinṣin yóò gbé ní ilé náààwọn aláìlẹ́gàn sì ni yóò máa wà lórí rẹ̀

22. ṣùgbọ́n a ó ké ènìyàn búburú kúrò lórí ilẹ̀ náàa ó sì ya àwọn aláìsòótọ́ kúrò lórí rẹ̀.

Òwe 2