Òwe 17:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹni tí ó fi talákà ṣe yẹ̀yẹ́ kórìíra ẹlẹ́dàá talákà náàẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ torí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.

6. Ọmọ-Ọmọ ni adé orí arúgbóòbí sì ni ìyangàn àwọn ọmọ.

7. Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aláìgbọ́n, mélòómélòó ni ètè tí ń parọ́ fún àwọn alákóso!

8. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ oògùn fún ẹni tí ó ń fún ni ohungbogbo, ibikíbi tí ó bá tẹ̀ sí ni ó ń yege.

Òwe 17