Òwe 17:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Aláìgbọ́n ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.

26. Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.

27. Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọènìyàn olóye sì máa ń ní ṣùúrù.

28. Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọgbọ́n bí ó bá dákẹ́àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.

Òwe 17