Òwe 16:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.

4. Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́Kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

5. Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.

6. Nípaṣẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀nípaṣẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

7. Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn-án bá a gbé ní àlàáfíà.

Òwe 16