Òwe 16:29-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.

30. Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte;ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.

31. Ewú orí jẹ́ ògoìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀.

32. Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ,ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ.

33. A ṣẹ́ kèké dàsí ìṣẹ́po aṣọ,ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

Òwe 16