Òwe 14:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,ṣùgbọ́n aláìgbọ́n obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ wó o.

2. Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa,ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.

3. Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàsán fún ẹ̀yìn rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

4. Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóníṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.

5. Ẹlẹ́rìí tí ń sòótọ́ kì í tan niṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.

6. Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.

Òwe 14