Òwe 11:26-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Àwọn ènìyàn a ṣépè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.

27. Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rereṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.

28. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú;ṣùgbọ́n Olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.

29. Ẹni tí ó ń mú ìdàámú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásánaláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún Ọlọgbọ́n.

30. Èṣo òdodo ni igi ìyèẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ Ọlọgbọ́n.

31. Bí àwọn Olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayémélòó mélòó ni aláìwà bí Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀.

Òwe 11