Òwe 11:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì déṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.

3. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìsòótọ́ wọn.

4. Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínúṣùgbọ́n òdodo a máa gba ni lọ́wọ́ ikú.

5. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọnṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fàá lulẹ̀.

6. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n làṣùgbọ́n ìdẹkùn ètè búburú mú aláìsòótọ́.

Òwe 11