15. Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu.
16. Obìnrin oníwà rere gba ìyìnṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
17. Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóoreṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.
18. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.
19. Olódodo tòótọ́ rí ìyèṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.
20. Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburúṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.
21. Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láì jìyà,ṣùgbọ́n àwọn Olódodo yóò lọ láì jìyà.
22. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.