Òwe 11:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú,ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu.

16. Obìnrin oníwà rere gba ìyìnṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.

17. Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóoreṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.

18. Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.

Òwe 11