Òwe 10:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà,ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀.

5. Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ,ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.

6. Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodoṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.

7. Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkúnṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.

8. Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.

9. Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwuṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.

10. Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkànAláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.

11. Ẹnu Olódodo jẹ́ oríṣun ìyèṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.

12. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

Òwe 10