Òwe 10:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a;Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.

25. Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ,ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.

26. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojúbẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.

27. Ìbẹ̀rù Olúwa ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá,ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.

28. Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.

Òwe 10