Òwe 10:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀,ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.

13. Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóyeṣùgbọ́n kùmọ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.

14. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.

15. Ọrọ̀ àwọn Olódodo ni ìlú olódi wọn,ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.

16. Èrè Olódodo ń mú ìyè wá fún wọnṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.

17. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hànṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn sìnà.

Òwe 10