Òwe 1:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ,má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;

16. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀,wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

17. Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ okùn de ẹyẹ,ní ìṣojú u gbó ẹyẹ!

18. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn.Ara wọn ni wọ́n ń dá lóhùn

19. Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́;yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọÌkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀

Òwe 1