7. Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,àti ọmú rẹ bí idì èso àjàrà.
8. Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ;Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú”Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,Àti èémi imú rẹ bí i ápù.
9. Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.Tí ó kúnná tí ó sì dùn,tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀
10. Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,èmí sì ni ẹni tí ó wù ú.
11. Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,Jẹ́ kí a lo àṣálẹ̀ ní àwọn ìletò
12. Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtùláti wo bí àjàrà rúwébí ìtànná àjàrà bá là.Àti bí póméegíránéètì bá ti rúdí,níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.