6. Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tóbáwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́!
7. Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,àti ọmú rẹ bí idì èso àjàrà.
8. Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ;Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú”Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,Àti èémi imú rẹ bí i ápù.
9. Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.Tí ó kúnná tí ó sì dùn,tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀