Orin Sólómónì 6:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Olùfẹ́ mi ti ṣọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀,sí ibi ibùsùn tùràrí,láti máa jẹ nínú ọgbàláti kó ìtànná lílì jọ.

3. Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi,Ó ń jẹ láàárin ìtànná lílì,

4. Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tírísà,Ìwọ lẹ́wà bí i Jérúsálẹ́mù,ìwọ lẹ́rù bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.

5. Yí ojú rẹ kúrò lára mi;nítorí ojú rẹ borí mi.Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gílíádì.

6. Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn,Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá,gbogbo wọn bí ìbejì,kò sì sí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn.

7. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bá ìbòjú rẹ,rí bí ẹ̀là èso pómégíránéètì.

8. Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀,àti ọgọ́rin àlè,àti àwọn wúndíá láìníye.

9. Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni,ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ,ààyò ẹyọkan ṣoṣo ẹni tí ó bí i.Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fúnÀwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fun-un

10. Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀,tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí òòrùn,tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?

11. Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igiláti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì,láti rí i bí àjàrà rúwé,tàbí bí pómégíránéètì ti rúdìí.

Orin Sólómónì 6