Orin Sólómónì 5:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣànsí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn

6. Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn

7. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ ìlú rí mibí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.Wọ́n nà mí, wọ́n ṣá mi lọ́gbẹ́;wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

Orin Sólómónì 5