Orin Sólómónì 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olùfẹ́ mi!Áá à ìwọ jẹ́ arẹwà.Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹIrun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́.Tí ó sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè Gílíádì.

2. Ẹyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbòtí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀;olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́;kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó yàgàn.

3. Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó;Ẹnu rẹ̀ dùn.Èrẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pàmógíránéètìlábẹ́ ìbòjú rẹ

4. Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dáfídì,tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra;lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún àpáta kọ́,gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.

5. Ọmú rẹ méjèèjì dàbí ọmọ ẹgbin méjìtí wọ́n jẹ́ ìbejìtí ń jẹ láàrin ìtànná lílì.

6. Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀tí òjìji yóò fi fò lọ,Èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjíáàti sí òkè kékeré tùràrí.

7. Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwa, olùfẹ́ mi;kò sì sí àbàwọ́n lára rẹ.

8. Kí a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì, ìyàwó mi,ki a lọ kúrò ní Lẹ́bánónì.Àwa wò láti orí òkè Ámánà,láti orí òkè ti Ṣénírì, àti téńté Hérímónì,láti ibi ihò àwọn kìnnìún,láti orí òkè ńlá àwọn ẹkùn.

9. Ìwọ ti gba ọkàn mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;Ìwọ ti gba ọkàn mipẹ̀lú ìwò ẹ̀ẹ̀kan ojú rẹ,pẹ̀lú ọ̀kan nínú ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ,

Orin Sólómónì 4