13. Ìdì òjíá ni olùfẹ́ mi jẹ sí mi.Òun ó sinmi lé àárin ọmú mi.
14. Bí ìdì ìtàná Hénínà ni Olùfẹ́ mi rí sí miLáti inú ọgbà àjàrà ti Énígédì.
15. Báwo ni o ti lẹ́wà tó, olùfẹ́ mi!Áá à, Báwo ni o ṣe lẹ́wà tó!Ìwọ ní ojú ẹyẹlé.
16. Báwo ni o ṣe dára tó, olùfẹ́ mi!Áá à, Báwo ni o ṣe wu ni!Ibùsùn wa ní ìtura.
17. Ìtànsán ilé wa jẹ́ ti igi kédárìẸkẹ́ ilé wa jẹ́ ti igi Fírì.