Oníwàásù 9:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ ọlọgbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n-ọn rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin talákà náà.

16. Nítorí náà mo ṣọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin talákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.

17. Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọgbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmú ṣeju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.

18. Ọgbọ́n dára ju ohun—èlò ogun lọ,ṣùgbọ́n ẹlẹ́ṣẹ̀ kan a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.

Oníwàásù 9