Oníwàásù 9:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé:Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburútàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùngẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibití ó ṣubú lù wọ́n láì rò tẹ́lẹ̀.

13. Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn:

14. Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yìí po, ó sì kọ́ ilé-ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì síi.

Oníwàásù 9