Oníwàásù 7:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọkàn ọlọgbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.

5. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.

6. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkòni ẹ̀rín òmùgọ̀,Aṣán sì ni eléyìí pẹ̀lú.

7. Ìrẹ́jẹ a máa ṣọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.

8. Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,ṣùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.

9. Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹnítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.

Oníwàásù 7