Oníwàásù 4:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá ṣùn pọ̀, wọn yóò móoru.Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?

12. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn-ún yàra fà já

13. Òtòsì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó ṣàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn,

14. Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde ìjọba, bí a tilẹ̀ bí i ní talákà ní ìjọba rẹ̀.

15. Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí.

Oníwàásù 4