Oníwàásù 2:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọgbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí òmùgọ̀? Ṣíbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú.

20. Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìṣimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn.

21. Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Aṣán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá.

Oníwàásù 2