Oníwàásù 10:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, ilé a máa wú,bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.

19. Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àṣè fún,wáìnì a máa mú ayé dùn,ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun—gbogbo.

20. Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ìbùsùn rẹ,nítorí pé ẹyẹ ojú—ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.

Oníwàásù 10