Onídájọ́ 9:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Bí àwọn ènìyàn yìí bá wà ní abẹ́ ìsàkóso mi ni! Ẹ̀yin ó bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín (Èmi yóò yọ Ábímélékì kúrò). Èmi ó ò wí fún Ábímélékì pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ”

30. Nígbà tí Ṣébúlù, alákoṣo ìlú náà gbọ́ ohun tí Gáálì ọmọ Ébédì sọ, inú bí i gidigidi.

31. Ó ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé, “Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣékémù ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti sọ̀tẹ̀ sí ọ.

32. Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó.

Onídájọ́ 9