Onídájọ́ 8:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Láti ibẹ̀, ó lọ sí Péníélì ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Súkótì ti dá a lóhùn.

9. Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Péníélì pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé èmi yóò wọ ilé ìṣọ́ yìí.”

10. Ní àsìkò náà Ṣébà àti Ṣálímúnà wà ní Kákórì pẹ̀lú ọmọogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà oòrùn, nítorí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.

Onídájọ́ 8