Onídájọ́ 6:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ańgẹ́lì Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí ańgẹ́lì náà mọ́.

22. Nígbà tí Gídíónì sì ti mọ̀ dájúdájú pé ańgẹ́lì Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run alágbára! Mo ti rí ańgẹ́lì Olúwa ní ojú korojú!”

23. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kú.”

Onídájọ́ 6