Onídájọ́ 21:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí pé nígbà tí wọ́n ka àwọn ènìyàn, wọ́n rí i pé kò sí ẹnìkan kan láti inú àwọn ará Jabesi-Gílíádì tí ó wà níbẹ̀.

10. Àwọn ìjọ ènìyàn náà sì rán ẹgbàá mẹ́fà àwọn jagunjagun ọkùnrin, lọ sí Jabesi Gílíádì wọ́n fún wọn ní àṣẹ pé, ẹ lọ fi idà kọlu gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́.

11. Wọ́n ní, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe, ẹ pa gbogbo ọkùnrin àti gbogbo obìnrin tí kì í ṣe wúndíá.”

Onídájọ́ 21